124
1.7K
58
0.19%
Se o mo wipe oruko ti won ba pe o le pinnu bi irin ajo aye re se maa ri? Ọkùnrin yii jẹ́ ẹni "iyì" ju àwọn arákùnrin rẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ìṣòro kan wà látì ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀ tí ó fẹ́ sọ ògo rẹ̀ di asán, Akiyesi Pataki: Ká Ìtàn Yii Dé Òpin, Kio Leè Ri Ẹkọ Nla Kọ Níbẹ.. Fi Ránṣẹ Ki Iwọna Gba Ìbùkún To Wà Níbẹ. Adara Fún Gbogbo Wa. Nígbà tí ìyá rẹ̀ bí i, ó kún fún ìrora gan-an. Nítorí ìrora yẹn, ìyá rẹ̀ sọ ọ́ ní "Jabeṣi," èyí tí ó túmọ̀ sí: "Ẹni tí a bí nínú ìbànújẹ́". Fojú inú wo ọmọdé kan tí wọ́n ń pè ní "Ìbànújẹ́" ní gbogbo ìgbà tí ó bá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ rere. Orúkọ rẹ̀ di ẹnu-ọ̀nà fún ìyà, ìjákulẹ̀, àti ìhámọ́. Bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ tó, ìbànújẹ́ ni èso iṣẹ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí Real Estate Consultant, mo mọ̀ pé "Boundary" tàbí ìhámọ́ lè pa iṣẹ́ ènìyàn mọ́ sínú kòtò. Ṣùgbọ́n Jabeṣi mọ aṣírí kan: Májẹ̀mú Ọlọ́run ju májẹ̀mú orúkọ tàbí ìpilẹ̀ṣẹ̀ lọ! Lọ́jọ́ kan, Jabeṣi kọ̀ láti tẹ̀síwájú nínú ìpọ́njú. Ó ké pe Ọlọ́run Ísírẹ́lì pẹ̀lú ohùn rara, ó sì gba àdúrà mẹ́rin tí ó mi ìpìlẹ̀ ọ̀run: 1. Ibukun: "Ìbùkún fún mi nítòótọ́". 2. Agbegbe Nla: "Sọ agbegbe mi di nla". (Expansion nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀!) 3. Agbara: "Kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi". 4. Aabo: "Pa mí mọ́ kúrò nínú ibi, kí ó má baà bà mí nínú jẹ́". Bibeli Sowipe: "Ọlọ́run sì fún un ní ohun tí ó tọrọ". Lójijì, ẹni tí wọ́n ń pè ní "Ìbànújẹ́" di "Alábùkún-fún". Ẹni tí wọ́n há mọ́ sínú ìhámọ́ di onílẹ̀ nlá tí ògo rẹ̀ tàn kárí ayé. Eko Pataki Tia Ri Ko Ninu Itan Yii🔥 - Ìbẹ̀rẹ̀ rẹ kò pinnu igbẹyin rẹ: Bí ìyá rẹ bá tiẹ̀ bí ọ sínú òṣì tàbí ìrora, Ọlọ́run lè tún ayé rẹ kọ. - Kókó Àdúrà "Specific" máa ń mú èsì wá: Jabeṣi kò kàn gbàdúrà lásán, ó sọ ohun tí ó fẹ́ gan-an nípa ìṣúnná owó rẹ̀ àti agbègbè rẹ̀. - O lè fẹ́ agbègbè rẹ lójú: Nínú iṣẹ́ rẹ, nínú owó rẹ, àti nínú ẹ̀mí rẹ, Ọlọ́run fẹ́ kí o ní "Expansion". Adura pẹlu ìgbàgbọ Gba Adura Jabesi Yii Fun Araare Pelu Igbagbo 1. Baba, gbogbo orúkọ tàbí àpèjẹ èsù tó ń tẹ̀lé mi kiri láti ìgbà èwe, pa wọ́n rẹ́ lónìí ní orúkọ Jésù! 2. Olúwa, bùkún fún mi nítòótọ́! Má ṣe jẹ́ kí ìbùkún mi mọ ní teminikan, jẹki okari ayé. 3. Baba, ìwọ ni Ọba tí ó ni gbogbo ayé, fẹ́ agbègbè mi lójú! Gbé mi láti ibi kékeré sí ibi gíga nínú iṣẹ́ mi. 4. Kí ọwọ́ rẹ tí ó ń gbe ni ga kí ó wà pẹ̀lú mi nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ mi nínú oṣù yìí. 5. Olúwa, pa mí mọ́ kúrò nínú gbogbo ibi tí ẹnu-ọ̀nà ọdún tuntun lè gbé dání. 6. Gbogbo ìrora àti wàhálà tí ó so mọ́ ọjọ ìbí mi, di ayọ̀ ayérayé lónìí! Bio Ba Gbagbo Wipe Olorun Ti Yi Aye Re Pa Si Rere, Se AMIN Kio Fi Ranse Si Group Adura Meta Pere Bayi. #inspirationalvideos #prayeroffaith🙏🙏 #howtopray #brodafire_ #interceed
124
1.7K
58
0.19%
Cost:
Manual Stats:
Include in groups:
Products: